Àkọsílẹ̀ Mátíù
10 Ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12), ó sì fún wọn ní àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́,+ kí wọ́n lè lé àwọn ẹ̀mí yìí jáde, kí wọ́n sì wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.
2 Orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà nìyí:+ Àkọ́kọ́, Símónì, tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù+ arákùnrin rẹ̀; Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù+ arákùnrin rẹ̀; 3 Fílípì àti Bátólómíù;+ Tọ́másì+ àti Mátíù+ agbowó orí; Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì; àti Tádéọ́sì; 4 Símónì tó jẹ́ Kánánéánì;* àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dalẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+
5 Àwọn méjìlá (12) yìí ni Jésù rán jáde, ó fún wọn ní àwọn ìtọ́ni yìí:+ “Ẹ má lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú Samáríà kankan;+ 6 kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni kí ẹ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.+ 7 Bí ẹ ṣe ń lọ, ẹ máa wàásù pé: ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’+ 8 Ẹ wo àwọn aláìsàn sàn,+ ẹ jí àwọn òkú dìde, ẹ mú kí àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, ẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni. 9 Ẹ má ṣe wá wúrà, fàdákà tàbí bàbà sínú àmùrè tí ẹ̀ ń kó owó sí,+ 10 tàbí àpò oúnjẹ fún ìrìn àjò náà tàbí aṣọ méjì,* bàtà tàbí ọ̀pá,+ torí oúnjẹ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+
11 “Tí ẹ bá wọ ìlú tàbí abúlé èyíkéyìí, ẹ wá ẹni yíyẹ kàn níbẹ̀, kí ẹ sì dúró síbẹ̀ títí ẹ fi máa kúrò.+ 12 Tí ẹ bá wọ ilé kan, ẹ kí àwọn ará ilé náà. 13 Tí ilé náà bá yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀;+ àmọ́ tí kò bá yẹ, kí àlàáfíà látọ̀dọ̀ yín pa dà sọ́dọ̀ yín. 14 Ibikíbi tí ẹnikẹ́ni ò bá ti gbà yín tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, tí ẹ bá ń kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú yẹn, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín dà nù.+ 15 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ilẹ̀ Sódómù àti Gòmórà+ máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ju ìlú yẹn lọ.
16 “Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò; torí náà, ẹ máa ṣọ́ra bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ bí àdàbà.+ 17 Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn èèyàn; torí wọ́n máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n á sì nà yín+ nínú àwọn sínágọ́gù wọn.+ 18 Wọ́n á tún mú yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba+ nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn àti àwọn orílẹ̀-èdè.+ 19 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn;+ 20 torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.+ 21 Bákan náà, arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n.+ 22 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á* dé òpin máa rí ìgbàlà.+ 23 Tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sí òmíràn;+ torí lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹ ò lè lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán títí Ọmọ èèyàn fi máa dé.
24 “Akẹ́kọ̀ọ́ ò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ẹrú ò sì ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.+ 25 Ó tó fún akẹ́kọ̀ọ́ kó dà bí olùkọ́ rẹ̀, kí ẹrú sì dà bí ọ̀gá rẹ̀.+ Tí àwọn èèyàn bá ti pe baálé ilé ní Béélísébúbù,*+ mélòómélòó wá ni àwọn ará ilé rẹ̀? 26 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù wọn, torí kò sí nǹkan tí a bò mọ́lẹ̀ tí a ò ní tú síta, kò sì sí ohun tó jẹ́ àṣírí tí a ò ní mọ̀.+ 27 Ohun tí mo sọ fún yín nínú òkùnkùn, ẹ sọ ọ́ nínú ìmọ́lẹ̀, ohun tí ẹ sì gbọ́ tí a sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ẹ wàásù rẹ̀ látorí ilé.+ 28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara àmọ́ tí wọn ò lè pa ọkàn;*+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tó lè pa ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ 29 Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí* ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀* láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.+ 30 Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà. 31 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.+
32 “Nítorí náà, gbogbo ẹni tó bá fi hàn pé òun mọ̀ mí níwájú àwọn èèyàn,+ èmi náà máa fi hàn pé mo mọ̀ ọ́n níwájú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 33 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi níwájú àwọn èèyàn, èmi náà máa sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 34 Ẹ má rò pé mo wá láti mú àlàáfíà wá sí ayé; ṣe ni mo wá láti mú idà wá,+ kì í ṣe àlàáfíà. 35 Torí mo wá láti fa ìpínyà, ọkùnrin sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.+ 36 Ní tòótọ́, àwọn ará ilé ẹni ló máa jẹ́ ọ̀tá ẹni. 37 Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ kò yẹ fún mi; ẹnikẹ́ni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin jù mí lọ kò yẹ fún mi.+ 38 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò yẹ fún mi.+ 39 Ẹnikẹ́ni tó bá rí ọkàn* rẹ̀ máa pàdánù rẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì pàdánù ọkàn* rẹ̀ nítorí mi máa rí i.+
40 “Ẹnikẹ́ni tó bá gbà yín gba èmi náà, ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ 41 Ẹnikẹ́ni tó bá gba wòlíì torí pé ó jẹ́ wòlíì máa gba èrè wòlíì,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gba olódodo torí pé ó jẹ́ olódodo máa gba èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tó bá fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí ní ife omi tútù lásán pé kó mu ún, torí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”+